FEED YOUR SPIRIT DAILY
THE SEED
“I am the living bread which came down from heaven: if any man eat of this bread, he shall live for ever: and the bread that I will give is my flesh, which I will give for the life of the world.” — John 6:51 (KJV)
Just as your body needs physical food to stay alive, your spirit needs the Word of God to remain strong and vibrant. When we neglect spiritual nourishment, we become weak, weary, and disconnected from God’s purpose. The Word of God is living bread. It never spoils, costs nothing, and is always available to those who hunger for it. Daily meditation and obedience to the Word bring strength, clarity, and deep satisfaction that nothing else can provide. Feed your spirit consistently through Scripture, prayer, and worship. A nourished spirit stands firm in trials and grows in intimacy with God.
Reflection: Your spiritual health depends on how you feed your spirit.
BIBLE READING: John 6:48–58
PRAYER: My God, help me to continually feed on Your Word so I may find satisfaction in You and live eternally. Amen.
FÚN Ẹ̀MÍ RẸ NÍ OÚNJẸ LOJOOJUMỌ́
IRUGBIN NAA:
“Èmi ni oúnjẹ ìyè náà, tí ó ti ọ̀run sọkalẹ wá; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé…” — Jòhánù 6:51
Gẹ́gẹ́ bí ara ṣe nílò oúnjẹ láti wà láàyè, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ nílò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti wà nínú agbára àti okun ninu ẹ̀mí. Tí a kò bá bìkítà nípa oúnjẹ tẹ̀mí, ìrẹ̀wẹ̀sí yóò dé, àárẹ̀ yóò bà wá, a ó sì yà kúrò nínú ìlànà Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni oúnjẹ ìyè. Kii n baje, kii n na eni lowo, beeni o si wa fun awon ti o ba n fe e. Ìṣàro ojoojúmọ́ nínú rẹ̀ àti ìgbọràn sí i ń fún ni ní agbára, ìmọ̀ tó jinlẹ̀, àti ìtẹ́lọ́run tí kò sí ohun mìíràn tó lè funni. Bọ́ ẹ̀mí rẹ nígbà gbogbo pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àdúrà, àti ìjọsìn. Ẹ̀mí tí a bá ti fún ní oúnjẹ yóò dúró ṣinṣin nínú ìdánwò, yóò sì dagba nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.
ÀṢÀRÒ: Ìlera rẹ nípa tẹ̀mí dúró lórí bi o se n fi ounje ẹ̀mí bọ́ọ.
BIBELI KIKA: Jòhánù 6:48–58
ADURA: Ọlọ́run mi, ràn mí lọ́wọ́ láti máa bọ ọkàn mi pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Rẹ nígbà gbogbo, kí n lè rí ìtẹ́lọ́run nínú Rẹ, kí n sì lè gbé ìgbésí ayérayé. Amin.