STEP OUT AND ACT IN FAITH
THE SEED
“Whoever watches the wind will not plant; whoever looks at the clouds will not reap.” Ecclesiastes 11:4 (NIV)
Excuses are the enemies of achievement. Many wait endlessly for perfect conditions that may never come, and as a result, delay their own breakthroughs. God’s promises are not for the idle but for those who act in faith. Waiting for ideal circumstances often masks fear or hesitation. But when we obey God despite uncertainties, His grace backs us up. Even a small step taken in faith can produce mighty results when God is involved. Stop delaying. Step out in faith, work diligently, and let God prosper your obedience.
Reflection: Don’t wait for perfect conditions—move in faith and see God work.
BIBLE READING: Philippians 2:14–15
PRAYER: Lord, help me to live a disciplined and focused life so I can become an achiever of good things. Amen.
JÁDE LỌ KÍ O SÍ GBE ÌGBÉSẸ̀ ÌGBÀGBỌ́
IRUGBIN NAA:
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kíyesi afẹ́fẹ́ kì yóò fúrúgbìn; àti ẹni tí ó bá ń wo àwọsánmà kì yóò ṣe ikore.” — Oníwàásù 11:4
Àwọn àwáwí ni ọ̀tá àṣeyọrí. Ọ̀pọ̀ ènìyàn dúró de ipò pípé tí ó lè máà dé, nítorí èyí, wọ́n sì ń fà á sẹ́yìn nínú àṣeyọrí wọn. Àwọn ìlérí Ọlọ́run kì í ṣe fún àwọn oníìmẹ́lẹ̀, bí kò ṣe fún àwọn tó ń gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Dídúró de ipò pípé sábà ń fi ìbẹ̀rù tàbí iyèméjì han. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ṣe ìgbọràn sí Ọlọ́run, oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ máa ń tẹ̀lé wa. Ìgbésẹ̀ kékeré kan nínú ìgbàgbọ́ lè yọrí sí àbájáde ńlá. Fí òpin sí idadúró. Jáde lọ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ṣiṣẹ́ takuntakun, kí o sì jẹ́ kí Ọlọ́run bukun ìgbọràn rẹ.
ÀṢÀRÒ: Má ṣe dúró de ipò pípé; gbe ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ ki o si ri iṣẹ́ Olorun.
BIBELI KIKA: Fílípì 2:14–15
ADURA: Oluwa, ràn mí lọ́wọ́ láti gbe ìgbésí ayé ìgbọràn àti àfojúsùn. Amin.