WALK IN FAITHFULNESS
THE SEED
“No, you yourselves do wrong and cheat, and you do these things to your brethren!” 1 Corinthians 6:8 (NKJV)
Faithfulness is one of the marks of a true believer. Unfortunately, some people allow greed and self-interest to lead them into cheating others even within the household of faith. Inflating prices, manipulating figures, or taking advantage of others for personal gain is unfaithfulness before God. God sees and rewards every action. Unfaithfulness may appear profitable at first, but it ultimately leads to loss – loss of trust, loss of integrity, and loss of God’s favour. True increase comes from walking in righteousness. Choose to live honestly and faithfully in all your dealings. Faithfulness brings honour before God and men, and it is a key to lasting blessings.
Reflection: Unfaithfulness may bring gain today but loss tomorrow.
BIBLE READING: Luke 16:10–13
PRAYER: Lord, purge my heart of every form of unfaithfulness. Help me to walk in integrity at all times. Amen.
RÌN NÍNÚ ÒTÍTỌ́
IRUGBIN NAA:
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ẹlòmíràn ní ìyà, ẹ sì ń rẹ̀ wọ́n ní jẹ, àní àwọn arákùnrin yín.” — 1 Kọ́ríńtì 6:8
Ìjọ́lọ́títọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àmì pàtàkì onígbàgbọ́ olódodo. Ó ṣeni láànú pé àwọn kan máa ń jẹ́ kí ojúkòkòrò àti ìfẹ́ ara ẹni darí wọn sí lílo ẹlòmíràn láǹfààní, àní láàárín ìdílé. Bóyá ó jẹ́ pẹ̀lú fífi owó ọja sókè láìtọ́, yíyí owó ètò ìṣúná pa dà, tàbí lílo ààyè lórí ẹlòmíràn fún èrè ara ẹni, gbogbo irú ìṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ àìṣòtítọ́ níwájú Ọlọ́run. Ọlọ́run rí gbogbo ìgbésẹ̀ wa, Ó sì ń san èrè gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa. Àìṣòtítọ́ lè dà bí ohun tí ń mú èrè wá lónìí, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó máa ń yọrí sí àdánù — ìpàdánù ìwà títọ́, ìpàdánù ojú rere Ọlọ́run, àti ìpàdánù ìtẹ́lọ́rùn ọkàn. Ìbùkún tòótọ́ ń wá láti inú rírìn nínú òdodo.
ÀṢÀRÒ: Àìṣòdodo lè mú èrè wá lónìí, ṣùgbọ́n àdánù ni ó máa ń yọrí sí ní ọ̀la.
BIBLE READING: Lúùkù 16:10–13
PRAYER: Olúwa, wẹ ọkàn mi mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà àìṣòtítọ́. Ràn mí lọ́wọ́ láti rìn nínú òtítọ́ ní gbogbo ìgbà. Amin.