YOUR WORDS SHAPE YOUR FUTURE
THE SEED
“Say to them, ‘As I live,’ says the LORD, ‘just what you have spoken in My hearing I will most certainly do to you.’” — Numbers 14:28 (AMP)
The Israelites’ fearful confession in the wilderness—“It’s better to die here”—became their reality. God tied their outcome to their words. The tongue can align with faith or with fear, and whichever it agrees with will steer the course of life. When trials come, resist the urge to speak fear, doubt, or frustration. Speak God’s promises with boldness. His Word is more powerful than the loudest storm. Let Scripture shape your language. Your words can either build your future with faith or limit it with fear.
Reflection: Your confession today is your experience tomorrow.
BIBLE READING: Numbers 14:26–35
PRAYER: Lord Jesus, help me to walk by faith and not by sight. Set a guard over my mouth so my words agree with Your promises. Amen.
ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ RẸ Ń MỌ ỌJỌ́ IWÁJÚ RẸ
IRUGBIN NAA:
“Sọ fún wọn, Bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.” — Númérì 14:28
Ìjẹ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ẹ̀rù ní aginjù wipe “Ó sàn láti kú síhìn” — pada wa si imuse fun wọn. Ọlọ́run so àbájáde wọn mọ́ ọ̀rọ̀ enu wọn. Ahọ́n lè bá ìgbàgbọ́ ṣiṣẹ́, tàbí kí ó bá ìbẹ̀rù ṣiṣẹ́ – èyíkéyìí tí a gba laaye ló máa darí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé. Nígbà tí àdánwò bá dé, ó rọrùn láti sọ ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù, iyèméjì, tàbí ìjàkulẹ̀. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ́ láti sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run pẹ̀lú ìgboyà. Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní agbára ju ìjì líle lọ. Jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ ṣe àtúnṣe èdè rẹ. Ọ̀rọ̀ rẹ lè kọ́ ọjọ́ iwájú rẹ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, tàbí kí ó fi òpin sí i nipa ìbẹ̀rù.
ÀṢÀRÒ: Ìjẹ́wọ́ rẹ lónìí ni yio di ìrírí rẹ ní ọ̀la.
BIBELI KIKA: Númérì 14:26–35
ADURA: Jesu Oluwa, ràn mí lọ́wọ́ láti rìn nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa ohun tí a fi ojú rí. Fi ẹ̀ṣọ́ sí ẹnu mi, kí ọ̀rọ̀ mi lè bá àwọn ìlérí Rẹ mu. Amin.