STRENGTH IN UNITY
THE SEED
“How good and pleasant it is when God’s people live together in unity!” — Psalm 133:1 (NIV)
Unity is the strength of the body of Christ. Just as a single broomstick is easily broken but a bundle is unbreakable, God’s people are strongest when they stand together. Unity magnifies our prayers, strengthens our witness, and frustrates the enemy’s plans. This unity does not happen by accident; it is built intentionally. It requires humility, patience, love, and the ability to celebrate our differences without division. It means refusing gossip, choosing understanding, and pursuing peace. When the Church walks in true unity, heaven rejoices, the world sees Christ in us, and blessings overflow.
Reflection: Unity is a powerful testimony of God’s love at work among His people.
BIBLE READING: Psalm 133:1–3
PRAYER: Father, thank You for the gift of unity. Strengthen the bond of love within Your Church and help me to be an agent of peace and harmony. Amen.
AGBARA TI NBE NINU ISOKAN
IRUGBIN NAA:
KIYESI i, o ti dara o si ti dùn to fun awọn ará lati ma jumọ gbe ni irẹpọ̀. ORIN DAFIDI 133:1
Isokan ni agbara ti mbe ninu eya ara Kristi. Gege bi eyo owo kan se rorun lati kan ti osu owo si soro lati kan, awon eniyan Olorun je alagbara pupo nigbati won ba wa ninu isokan. Isokan maa ngbe adura wa goke, o nfi agbara fun wa nigbati a ba saare, a si maa nba imo ota je. Isokan yii kii dede waye, a maa n fisokan lati se ni. O nilo irele, suuru, ife ati agbara lati mo ailera onikalulu laisi iyapa. O tumosi pe a maa yera fun oro eyin, nini oye ati lilepa alafia. Nigbati ijo ba wa ni isokan lotito, orun nyo, aye yio ri Kristi ninu wa, ibukun wa yio si kun akunwosile.
ERO: Isokan je eri ti o lagbara nipa ife Olorun ti nsise laarin awon eniyan Re.
BIBELI KIKA: ORIN DAFIDI 133:1-3
ADURA: Baba, O seun fun ebun isokan. Mu ki okun ife ki o le si ninu ijo Re, ki O si ranmilowo lati je eni alafia ati irepo. Amin