NUMBER YOUR DAYS
THE SEED
“So teach us to number our days, that we may apply our hearts unto wisdom.” — Psalm 90:12 KJV
Life is brief and fragile, and numbering our days means living with purpose and wisdom. Moses reminds us that our time on earth is short, and only what is done for God will last. Each day is a gift and an opportunity to align with God’s plan. When we reflect on the brevity of life, we learn to prioritize rightly—placing our relationship with God above everything else. Numbering our days stirs repentance, gratitude, and a desire to make each moment count. Those who live wisely store treasures in heaven, not just on earth. When you live with eternity in view, your daily decisions carry lasting weight. If today were your last, how would you spend it?
BIBLE READINGS: Psalm 39:4
PRAYER: Lord, teach me to live with a wise heart and eternal focus. Amen.
KÍ A MÁA KÀ ỌJỌ́ WA
IRUGBIN NAA
“Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.” Orin. Daf 90:12 YBCV
Ayé jẹ́ kékere tí kò si dúró pẹ́, ìtumọ̀ kìkà ọjọ́ wa ni wipé ká gbé ayé pẹ̀lú óye àti ìdí. Mósè rán wa leti pé ìgbé ayé wa lórí ayé ko pẹ rara, àti pé ohun tí a ṣe fún Ọlọrun nìkan ni yóò dúró títí ayé. Gbogbo ọjọ́ jẹ́ ẹ̀bùn, àti àǹfààní láti yà ara wa sọtọ sí mímú ìfẹ́ Ọlọrun ṣẹ. Nígbà tí a bá rántí pé igbeayé ko pẹ, a o kọ́ láti ma a ṣe ohun tó tọ́ nikan, a o sì máa fi Ọlọrun sí ipò àkọ́kọ́ nínú gbogbo ohun. Ìmọ̀lára pé ayé wa kù díẹ̀ ń mú wa ní ìrònúpìwàdà, ìdúpẹ́, àti ìfẹ́ láti lo gbogbo ìṣẹ́jú ní ìmóye. Àwọn tó ń gbé igbe ayé ọgbọ́n ni wọ́n ń pa ìṣúra wọn mọ́ ní ọ̀run, kì í ṣe ní ayé nìkan. Bí a bá gbé ayé pẹ̀lú ìran àìnípẹ̀kun, gbogbo ìpinnu wa yóò ní itumọ tí o yẹ. Bí òní bá jẹ́ ọjọ́ rẹ̀ tó kẹ́yìn, báwo ni ìwọ yóò ṣe lo o?
BIBELI KIKA: Orin. Daf. 39:4-7
ADURA: Oluwa, kọ́ mi láti gbé ayé pẹ̀lú ọkàn ọgbọ́n àti ìfọkànsìn àìnípẹ̀kun. Àmín.