THE ACCUSER OF THE BRETHREN
THE SEED
“…For the accuser of our brothers and sisters, who accuses them before our God day and night, has been hurled down.” Revelation 12:10 NIV
Satan accuses; Jesus intercedes. The devil’s testimony is disqualified Jesus called him the father of lies (John 8:44). In heaven’s court the Judge justifies us, and the Son defends us (Rom. 8:33–34). If God has declared you righteous in Christ, no accusation can overturn that verdict.
Condemnation chains the forgiven; the gospel breaks those chains. When the enemy drags your past into today, point to the cross and the blood that speaks a better word. Agree quickly with God about sin, receive cleansing, and then refuse to rehearse what God has already removed.
Live as the acquitted: worship boldly, serve freely, and stand firm in the word of your testimony. The accuser has been cast down; walk in the freedom Christ secured. Don’t accept in your heart what God has thrown out of His court.
BIBLE READINGS: Romans 8:31–39
PRAYER: Father, I reject Satan’s accusations and rest in Christ’s justification. Thank You for my freedom in Jesus. Amen.
OLÙFISÙN ARÁ
IRUGBIN NAA
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè: “Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kristi rẹ̀. Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde, tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru. – Ifihan 12:10
Satani ni n finisùn, Jesu si n gbèjà wa. Ẹ̀rí sátánì ni a ti fagi lé – Jesu tilè pee ni baba èké (Johanu 8:44). Ni ìtẹ́ idajo ti orun, Oludajo da wa lare, Jesu si n gba ejọ́ wa rò (Romu 8: 33-34). Ti Olorun ba ti sọ ọ di olododo ninu Kristi, ko tun si ifisun kan ti o le yi̒i pada. Ẹ̀bi a maa de eni ti a ti dariji, ihinrere a si ma ja awon ide yii. Nigba ti ota ba rán o leti igba atijo re, tọ́ka si agbelebu ati ẹ̀jẹ̀ ti n so oun to dara. Gbo ikilo Olorun si o nipa ẹ̀ṣ̀ẹ̀, gba iwenumo, ki o si sora lati mase pada si ohun ti Olorun ti gba o kuro ninu re. Máa gbe bi eni ti a da lare: máa sin pelu igboya ati pelu ominira, ki o si duro sinsin ninu oro ẹ̀rị́. Olufisun ni a ti le jade; máa rin ninu ominira ti Kristi se fun o. Ma tun gba oun ti Olorun ti mu kuro pada si okan re.
BIBELI KIKA: Roomu 8: 31-39
ADURA: Baba, mo kọ ifisun satani, mo si fara mo idalare ti Kristi. E ṣẹ́ fun ominira mi ninu Kristi. Amin.