TRUSTING GOD THROUGH PAIN
THE SEED
“Eli answered, ‘Go in peace, and may the God of Israel grant you what you have asked of Him.’” — 1 Samuel 1:17 NIV
Hannah’s pain was deep, but her faith was deeper. Though mocked and misunderstood, she poured out her soul to God. Her story reminds us that God often works through our pain to bring forth His greater purpose. Hannah’s persistence in prayer, trust in divine timing, and honouring of spiritual authority positioned her for a breakthrough. God not only gave her Samuel, but made him a prophet to a nation. Pain should never silence prayer. When we bring our anguish to God, He turns it into testimonies. Trusting Him through tears is often the pathway to joy.
How can your pain become a platform for God’s power to be revealed?
BIBLE READINGS: 1 Samuel 1:9–20
PRAYER: Lord, help me to trust Your timing even through pain. Turn my tears to testimonies. Amen.
ÌGBẸ́KẸ̀LÉ ỌLỌ́RUN NÍGBÀ ÌRORA
IRUGBIN NAA
“Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ.” I. Sam 1:17 YBCV
Ìrora Hánná jinlẹ̀ gidi gan-an, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ sí i ju ìrora rẹ lọ. Bí o tilẹ jẹ wipe wọ́n fi i ṣe ẹlẹya, o si ri aigboniye, sibẹ kò kúrò níwájú Ọlọ́run; ó tú ọkàn rẹ̀ jáde níwájú Rẹ. Ìtàn Hánná ń rán wa leti pé Ọlọ́run sábà máa ń lo ìrora wa láti mú idi rere Rẹ ṣẹ. Ìfaradà rẹ̀ nínú àdúrà, ìgbọràn sí àkókò Ọlọ́run, àti ìbòwọ̀ fún woli ló ṣí ọ̀nà ìbùkún fún un. Kì í ṣe pé Ọlọ́run fún un ní Samuel nìkan, ṣùgbọ́n ó tún fi Samuel ṣe wòlíì fún orílẹ̀-èdè Rẹ. Ìrora kò gbọ́dọ̀ dá wa duro ninu àdúrà; nígbàti a bá mú ìrora wa wá síwájú Ọlọ́run, O máa yí i padà sí ẹ̀rí rere. Ìgbọ́kànlé sí Ọlọ́run nígbà ẹkun àti ìbànújẹ sábà máa ń di ọ̀nà sí ayọ̀ tó jinlẹ̀. Báwo ni ìrora rẹ ṣe lè e di pẹpẹ fún agbára Ọlọ́run láti hàn gbangba?
BIBELI KIKA: 1 Samuel 1:9–20
ADURA: Olúwa, jọ̀wọ́, ràn mí lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀lé àkókò Rẹ paapaa nígbà ìrora. Yí omijé mi padà sí ẹ̀rí rere. Àmín.